17/05/2023
Eda eniyan ti nlepa lati leyin kuro laye, loni, alagbara Israeli mu kuro loke eepe, eniyan ika to ndana ikoro nitori yin, Oluwa fi ikoro bóo ni àbóyó, àsá okunkun to nlepa lati gbe yin t'omo-t'omo, ofa Oluwa ko wo'le sii lara, ikooko apanirun to farasin loju ona yin, Oluwa faa ya pere-pere, asepari ise okunkun laye yin, ina Oluwa laa koja, imule ati if'ohunsokan awon eniyan buburu ni Oluwa tuka, gbogbo àfòmó ogun ninu irin ajo aye yin ni Oluwa si fi ina sun patapata.
Gbolohun ko seese di asan lori yin, idaduro parada di itesiwaju, ohunrere gbogbo ti aye yin ya'gan re, Oluwa soo di òpò fun yin, ohunrere koni fa seyin laye yin, ayo Olorun yoo si po ninu idile yin loruko Jesu Kristi. Alaafia fun yin