08/12/2025
Ose pegunrun ( Akose Okanran Eguntan)
Ao jo eeru oju aro, ao daa soju opon ifa tabi awo funfun to fe, ao te odu Okanran Eguntan si, ao pe psalm re si, leyin naa ao po eeru yen mose iwe eekan soso, ao mu sori kahinkahin, o di wiwe ninu odo to n San.
Psalm re:
Ti ise ba seni laseju
Ebi eni a ko Ni
Ti ise ba seni laseju
Ara eni a ko Ni
Ti ise ba seni laseju
Baba ati iya eni a ko Ni
A dia f'okanran Ose
Tii lo ree dase nu lodo
Ebo lawo ni ko wa SE
O gbo riru ebo o rubo
O gbo titu etutu o tu
Igba to de odo
Lo ba wese nu
O ni mo dodo mo wese nu
Ise mi tan oro lo ku
Mo denu eri mo wese nu ooo.
NB: A kìí se ose yi pamon sinu ile
Oojo ni wiwe re ninu odo to n San
Bi a se n te odu naa:
l ll
ll ll
l ll
ll l
Iba oluwo ajero 🙇. Mo gba adura wipe gbogbo egun ojo pipe to n bawa finra a dohun igbagbe ki odun yi to pari. Alaafia 🕊️ 🌴🙇