08/05/2023
Gbogbo ìbùdó ikorajo po okunkun nitori yin, aara Oluwa la ibe koja, pepe ti okunkun te nitori yin, Oluwa ya pepe naa, ikorajo po awon eniyan lasan lori yin, ibinu Oluwa ru si won, eda ika to ni irin ajo yin koni jinna, Oluwa fi emi re rubo, eniyan buburu to nf'owo so'ya lodi lori yin, Oluwa dide lodi si won, ogun to duro de yin ni ikorita lati jehun omo tabi aseyori yin, loni, Oluwa se ogun naa wole patapata, eni to npe ara re ni olorun lori aye yin, ijoba re faya, ikoro koni yi wo aye yin, iku koni se aseyori lori yin, idaamu koni nipa lori yin, bi e se nwonu osu karun, ofa ota koni wole si yin lara, òfò emi ati t'ara koni se yin, gbogbo ijoba aninilara lori yin, Oluwa faa ya, ninu irin ajo ose yi, iku koni kayin mo, ogun aruka koni bori yin, ekun at'eyinwa yin yoo di eri, iku rewerewe koni payin, idile yin koni wo'nu ogun, iji idaloro koni ja yin, afefe odi koni fe lu yin, alaafia pipe yoo si kun aye yin loruko Jesu Kristi.