07/12/2023
ITAN ANABI MUSA (MOSE)
Ànábì Mūsā jẹ ọmọ Imrọ̄n ọmọ Yaskhar ọmọ Qọ̄'has ọmọ Lā'awy ọmọ ànábì Ya‘ƙūb ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa baa.
Nígbàtí Imrọ̄n pe ọmọ ọdún (137 years) ni Ọlọhun yọnda Ànábì Mūsā fun-un.
Fir'aon akọkọ ní ìlú Misrọ̄ gba Islam lati ọwọ ànábì Yūsuf, lẹyìn tí Fir'aon akọkọ ku, báyìí ni ọmọ ìyá rẹ (Abul Abass) Fir'aon ẹlẹ́ẹ̀kejì náà jẹ ọba, Ànábì Yūsuf pé e si inú Islam, sùgbọ́n Fir'aon ẹlẹ́ẹ̀kejì yẹn ya aláìgbàgbọ, nínú àsìkò ti n'se ìjọba lọwọ ni Ọlọhun ọba gba ẹmi Ànábì Yūsuf, ọba yìí pẹ diẹ lórí oyè, lẹyìn tí ohùn náà jáde kúrò ní ilé aiyé, ọmọ ìyá tirẹ náà (Qọọbuus) ló tún gba ìjọba.
Ẹsìn Islam ni ẹsìn ti àwọn ọmọ Isrọ̄’īl n'se, t**i ti Fir'aon Ànábì Mūsā fí de, Fir'aon Mūsā ko àwọn ọmọ Isrọ̄’īl ní ẹru, n̄g sí n'fi ìyà jẹ wọn, O sí sọ ara rẹ di ọlọhun le àwọn ọmọ Isrọ̄’īl ni orí, wípé kí wọn má jọsìn fún ohùn pẹlú tipatikuuku, ìdájọ iku si ni Fir'aon n'da fún gbogbo ẹnikẹni tí O ba ta ipa sí òfin rẹ, ìyà burúkú ni Fir'aon n'fi jẹ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl.
Fir'aon fẹ ìyàwó kàn ti orúkọ rẹ n'jẹ A'asiyāt ọmọ Maza'āmi ọmọ An'biyd, ọmọ Royyaān, ọmọ Wa'liyd, ọmọ Fir'aon akọkọ tíìse ọrẹ Ànábì Yūsuf, A'asiyāt pada gba ẹsìn Islam láti ọwọ ànábì Mūsā - ki ikẹ ati Ọla Ọlọhun (Allāhu) máa bá a.
Láàrin ọgọ́rùn mẹ́rin ọdun, ni ìyà burúkú fí jẹ àwọn ọmọ Isrọ̄’īl, Fir'aon bá ilẹ jẹ púpọ̀, O sí ṣègbéraga lórí ilẹ, (Quran 10 Verse 83)
(Dájúdájú Fir‘aon kúkú ṣègbéraga lórí ilẹ̀, àti pé, dájúdájú ó wà nínú àwọn alákọyọ)
Ni ọjọ kàn, báyìí ni Fir'aon la àlá wípé: iná kàn jáde láti inu Mọ́ṣálásí Daru-Salam (Jerúsálẹ́mù), iná náà sí jo gbogbo ile tí wọn n'bẹ ní ìlú Misrọ̄, sùgbọ́n iná náà ko sí jo awọn ọmọ Isrọ̄’īl, báyìí ni Fir'aon pe àwọn adàbigba àti àwọn amòye rẹ láti wà sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ohùn.
ITAN NTESIWAJU