Alawosan tradoherbal/spritual healing home

Alawosan tradoherbal/spritual healing home our herbal is make.sense and reach to cure any ailment u have pls tested and trusted .

09/07/2021

ODÙ IFÁ ÒDÍ- Ọ̀KÀNRÀN

Ọ̀ṣà wọ́n sun bí eyá
Kùtùkùtù ò mú'lẹ̀ ṣe bìsàbìsà
Ló dífá fún Aríléwọ́lá
Ọlọ́mọ ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀rin àmọ ìmọ àrà

Wọ́n ní oṣù mẹ́rin ló kù
tí Ọlọ́run máa lànà ìwà fún un
Ṣùgbọ́n pé kí ó rú ẹbọ ewu ọdún mẹ́rin
Nítorí ikú òjijì nígbàtí ààyè bá máa gbàá tán
Kó má bàa kú ní àkókò tí Orí rẹ̀ yóò dára.
Wọ́n ní kó fi ọkọ́ kan, àgàro kan,
àti ogigi kan rú ẹbọ.

Aríléwọ́lá pe ifá lékèé
Ó pe Èṣù lólè
Ó fi etí àdí gbọ́rọ̀.
Aríléwọ́lá kọ̀, kò rú ẹbọ.

Nígbàtí oṣù mẹ́rin pé gẹ́gẹ́ bí ifá ti wí,
Aráyé fi Aríléwọ́lá j'ọba.
Ó gorí oyè, ó sì ní gbogbo ǹkan ọlà dọ́mọdọ́mọ.
Aríléwọ́lá sì kọ́ ilé aláràǹbarà,
a-gbójú-sókè-wò bí ọ̀nà ọ̀run.
Ó sì fi èyí ṣe ibùgbé pẹ̀lú gbogbo ọmọ rẹ̀
bí wọ́n ṣe pọ̀ tó.

Àwọn ọmọ rẹ̀ wá pèé,
Wọ́n ní "bàbá wa, wọ́n ní kí o rú ẹbọ ewu ọdún mẹ́rin, nítorí ikú tí ifá wí".
Aríléwọ́lá ní kàkà kí ikú pa òun,
òun yóò fi igba ẹrú wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ dílé
Ó ní kàkà kí ikú pa òun,
Òun yóò fi ẹgbẹ̀rin korokoro ènìyàn dónà.
Ó ní kàkà kí ikú ó pa òun,
Òun yóò lọ sí àjà ilé òun,
tí òun yóò sì ṣe minimini sí

Nígbà tí ó di àkókò ní inú ọdún mẹ́rin àìrúbọ,
Èṣù Ẹlẹ́gbára bá dìde, pẹ̀lú àṣẹ Olódùmarè,
Ó kó àwọn iginniganni jànmọ́ọ̀ lẹ́yìn.
Èṣù kó ọkọ́, àgàro àti ogigi lé wọn lọ́wọ́.
Èṣù ní kí wọ́n máa nìṣó nílé Aríléwọ́lá náà.

Ó ní kí wọ́n máa wó ilé rẹ̀ bolẹ̀
Tọkọ́tọkọ́, tàgàro tàgàro, tògìgí tògìgí
Báyìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wó ilé Aríléwọ́lá.
Wọ́n sì bá Aríléwọ́lá ní àjà ilé náà,
tó ṣe minimini sí, wọ́n sì mú u,
Wọ́n sì pa á sun jẹ.

Aríléwọ́lá ni orúkọ tí à ń pe olú ọ̀gán tàbí ọba ikán. Láti ìgbà náà ni aráyé ti máa ń fi ọkọ́, àgàro àti ògiri wó ilé ọ̀gán. Tí wọ́n sì máa mú olú ọ̀gán pa sun'jẹ.

Ifá ń wípé, kí gbogbo wa máa ṣe àkíyèsí pàtàkì nítorí àwọn elénìní ayé. Kí wọ́n má ba lè ba iṣẹ́ ọwó ẹni jẹ́, pàápàá nígbàtí ó bá ń dára fún'ni.
Ifá ṣe àtẹnumọ́ pàtàkì nínú odù yí, wípé lẹ́yìn tí a bá rí oore gbà, ewu sì ńbẹ fún ọdún mẹ́rin.

Olódùmarè yóò máa fi ìṣọ́ rẹ̀ sọ́ wa t'ọmọ t'ọmọ,
A ò ní gbé'lé gb'ọfà láì r'ogun.

©️Ajay Kanago

07/03/2021

tis s my was app numner

09/09/2020
24/08/2020

egbogi ajebidan watch out

05/03/2019

Iyonu owo todaju ikunojia Oroagogo epoobo osefunfun ao gunpo aopa tangiri ni pansa aokosinu re a o gbe sinu a*o funfun wiwe danwo kopemi

12/08/2018

Aleko todaju itakun OPE itakun agbon Egbo gboin gboin ogede dudu aore ni oti mimun

Address

Ijaye Road
Lagos

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Alawosan tradoherbal/spritual healing home posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Share